Happy birthday Ejire ara Isokun
Edun A gbori igi regrege
Winino winini loju orogun
Eji woro loju iya e
O be kisi be kese
O be sile elekisa
O so o dalaso
Okan mo ni n o bi
Eji lo wole to mi
Bu mi ki nba o releYin mi ki npada leyin re
Nijo ejire ti daye ko jale ri
Oju oloko ni se je tie
Mo lepo nile
Mo lewa loode
Ejire eelaki maa bo lodo mi
Ireke mi ree
Aadun mi ree
Mo fe bo ibeji oro
Oniruuru omo lo nbe laye
Ninu omo to je abami
Comments
Post a Comment